Baba mi ni Eledumare, Olorun Agbalagba, Olorun Agba-Oye, Oyigiyigi, Olowo gbogboro, Eleti lu kara bi ajere, Adani ma gbagbe eni, Alagbawi eda, Alese le wi!” 

Alewi le se, Adagba ma paro oye, Oyigiyigi, Olu Orun, Aterere kari aye, Alagbada ina, Kabi-o-osi….awa juba re oooooo…….

Apata Ayeraye, Imole ti ko le ku laye, Olurapada aye, Awimayehun, Aseda aye, Oba t’o le se oun gbogbo, Oba ti kii sun, Oba ti kii re… Ah! Taa la ba fi Baba we?!

Arugbo ojo, kiniun eya Judah, Ikini ati Ikeyin, Ajipojo iku da, Kabio osi, Oranmo nise fayati, Asoro kolu bi ogiri oke, Alagbala imole, Olori Ariran, Adagba ma tepa, Ajade nile ma tan nile…………….Ta lo le ba dogba?

Alagbada ina…Awimayehun, Alewilese, Asoromatase..Eletigbarooye…Oba to fo’run se aso ibora, Eleburu ike, Oyigigi Kabio osi, Ibare maa re aribiti arabata….Ope ye o Baba!

Kini mba se fun Olorun ti ko je ki ese mi o ye. Oluwa ti ki i toogbe, ti ki i sun lori oro mi? Baba mi ni Ojiji mi ati Owo otun mi. Oba ti n soro ninu owon awo-sanma. Orun ni ite re, aye ni apoti itise re. Ki ohun gbogbo ti o ni eemi yin Oluwa, Eledumare logo!

Ohun ni oun gbogbo ninu oun gbogbo tosi le se oun gbogbo…ari iranala Olodumare, Oba gbani gbani tan sa ba, oluda aye ati orun, iba ooo iba.

Erujeje tin mi gbo kiji kiji, alade wura, adeda, aseda, oba ti n je emi ni emi ni, oba ti n je emi ni mase beru, eleti n gbo aroye eda, afa omega, aterere kari aye, apata ayeraye, alade wura.

E jowo e ba mi gbe Baba yii laruge, Oun nikan ni gbogbo ogo ye. Oun ni Asokoribe, Jagunjagun ti n ja aja ye, Gbanigbani ti n gba eniyan lowo okunkun. Oba to n damilola, to n segunfunmi, to n timilehin, O ba ti n gbe nu Wundia sola. Alagbara ninu awon orun, Oba ti o ti wa ki aiye to wa. Oba ti o wa, nigba ti aiye ko si mo. Gbirin leyin asododo. Gbagba gba leyin asooto. Oka soso adaba ti nmi igbo kiji kiji. Eru Jeje ti nbe leti okun pupa. Oju kan nti wo igba aye. Olorun ajulo, atobiju. Aye ka o won ko ri e ka. Aye wa o titi wo ko ri o. Olorun ti ki rin irin ajo oba ti ko si ipo pada. Ibere Ogbon, Opin Imo. Atofarati bi oke. arinu rode, Olumoran okan. Alapanla to so ile aye ro. Akiikitan, Ayi-Yintan, Ape-Petan, Eleru niyin. Olutunu, Olugbeja, Oludande, Olupamo, Olukoni, Olupese, Olubukun.Oba ti n ti ilekun ti eda kan ko le si, Oba ti si ilekun ti eda kan ko le ti. Ebeniseri! Niyin l’Oluwa ran mi lowo de O!

SHARE
Previous articleDubious sign
Next articleDespite Everything, I celebrate Naija
African woman, lawyer, teacher, poet and researcher. Singer of songs, writer of words, very occasional dancer of dances. I seek new ways of interpreting the African experience within our consciousness to challenge static ideology.

1 COMMENT

Leave a Reply, Foluke would love to hear your thoughts on this post